Sunday, June 5, 2011

OKO OJU OMI OMIJE (The Ship of Tears Yoruba Version)


Okò ojú omi ti omijé
Ikoko ti idakeroro
Pelu omije ti o jinle
Eyiti o wa lati inu irora
Lati inu agbami ironu
Ti o jinle ninu okan mi

Èrò tí o ńso jáde
Lati ala ti o buru
Eyiti o ti ru s’oke
lati ojo si ojo,
Ti o nipon ti o si ga
Ninu okan jinjin
            
Isan ironu kan,
Ro yika lati inu òrò ti a gbe
Ti o dabi oko
Si okan mi ti o si daa lu
Ani ibi ti o le pupo
Ninu emi mi

A! bawo ni okan mi
ti gbogbe to
Nigbati omije wooro rogba
Yi gbogbo ereke mi
Ti o sin san de
Igba aya mi

Bi mo si ti n la ibu
Koja lori agbami
Ni agbabu
oko omije
Ni opolopo ojo
Ati paapa ose.

Emi o tan
atupa elepo
Ng o si la ibu ja
Laarin okun inira,
Ni ireti ati tete de
Ebute alaafia

Sibe emi ko ni
Yo omi na lenu rara.
Emi yo rora koja jeje
Ng o si ri pe
Bi mo ti nkoja lo
Mo ni itelorun sibe.

Ó Gbeminiyi Alli 2009

Read English version - The Ship of Tears